Idowu Oroye

Biography: I am a Christian, a proud Yoruba boy and someone who is passionate about writing poems that are didactic and morally uplifting. I am on Facebook and Twitter: @IdOroye

Idowu Oroye's Profile


Idowu Oroye
Tuesday 9 February 2021

OGÚN

Mo fẹ́ d'ogún, mo fẹ́ d'ọgbọ̀n nílé ayé,

Ọjọ́ a bá p'ojúdé náà l'ódìgbóóṣe.

Òtítọ́ sì ni wípé:

Ogún tí ò d'ògún

lé gbọ̀n t'óbá d'ọgbọ̀n,

Tàbí kóta l'áàdọ́ta.

Bí kò sì rún l'ọ́gọ̀rún,

Á rún títí ọ̀ọ́dúnrún.

 

Àsìkò wa nílé ayé - bi idì tí ń fò,

Ọjọ́ ayé wa - àfi bí àlá,

Àní Elédùà nìkan l'ó mon ẹní máa là.

Kìkì kí á ti ṣe rere,

K'á sì gbé pèlú ìmọ̀ yíì wípé:

 

Bí ìgba wa láyé bá tilẹ̀ jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogún,

B'ótile wù k'ógùn tó,

Ìṣeun ìfẹ́ wa l'áyé ọmọlàkejì,

Òun nìkan ṣáà l'ogún tó dárajù

t'a le fi sílẹ̀ nígbà

t'ẹlẹ́kò ọ̀run bá polówó síwa.

 

ENGLISH TRANSLATION


The quest to be rich and famous,

Calls farewell when our eyes close.

And this is true:

A twenty that is not rusty

can get shaky by thirty,

Or be burning at fifty.

And if it is not blasted at a hundred,

It sure will, before three hundred.

 

Our time here - as an eagle that flies,

Our life - like a dream.

The Almighty alone knows who will succeed. 

Only for us to do good,

And live knowing that:

 

If our lifetime is many twenties,

No matter how plenty,

Our benevolence and charity

alone is the best heritage

we can part with,

When death calls unto us. 

 

Audio version available on Audiomack: https://audiomack.com/idoroye/song/ogun

© ÒRÓYÈ ÌDÒWÚ DAVID



4
3891 Views

Trending Now


Most Rated Poems


Recently Joined


FPG Feeds



>